Acts 19:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ nítorí náà tí Démétíríù, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn-asọ̀ kan sí ẹnìkẹ́ni, ilé-ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn.