Acts 19:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ṣe agídí, tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ọ̀nà Oluwa níwájú gbogbo àwùjọ, Paulu yẹra kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ sí gbọ̀ngàn Tirani, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lojoojumọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoójúmọ́ ni ilé-ìwé Tíráńnù.