Acts 2:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi nítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Dafidi ti wi nipa tirẹ̀ pe, Mo ri Oluwa nigba-gbogbo niwaju mi, nitoriti o mbẹ li ọwọ́ ọtún mi, ki a mà bà ṣí mi ni ipò:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo niwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, A kì ó ṣí mi ní ipò.