Acts 20:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ ṣí Makedóníà.