Acts 20:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Paulu sá ti pinnu rẹ̀ lati mu ọkọ̀ lọ niha Efesu, nitori ki o ma ba fi igba na joko ni Asia: nitori o nyára bi yio ṣe iṣe fun u, lati wà ni Jerusalemu li ọjọ Pentikosti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pọ́ọ̀lù ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀-ojú omi kọjá ṣí Éféṣù, nítorí ki ó má baà lo àkókò kankan ni Éṣíà: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣééṣe fún un láti wà ní Jerúsálémù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì.