Acts 20:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sopateru ara Berea ọmọ Parru si ba a lọ de Asia; ati ninu awọn ara Tessalonika, Aristarku on Sekundu; ati Gaiu ara Derbe, ati Timotiu; ati ara Asia, Tikiku on Trofimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sópátérù ará Béríà ọmọ Páríù sì bá a lọ dé Éṣíà; àti Sékúńdù; àti Gáíúṣì ará Dábè, àti Tìmótíù; ará Éṣíà, Tíkíkù àti Tírófímù.