Acts 20:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọjọ́ ìkínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ijọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárin ọ̀gànjọ́.