Acts 20:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọdọmọkunrin kan ti a npè ni Eutiku si joko li oju ferese, orun si wọ̀ ọ lara: bi Paulu si ti pẹ ni iwasu, o ta gbọ́ngbọ́n loju orun, o ṣubu lati oke kẹta wá silẹ, a si gbé e dide li okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Éútíkù sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Pọ́ọ̀lù sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n lójú oorun, ó súbù láti òkè kẹ́ta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú.