Acts 21:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú ọ̀já ìgbànú Paulu, ó fi de ara rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní, “Ẹ gbọ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí: Báyìí ni àwọn Juu yóo di ọkunrin tí ó ni ọ̀já ìgbànú yìí ní Jerusalẹmu; wọn yóo sì fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀ li ọwọ́ on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́ wi, Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹṣẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerúsálémù yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fí i lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”