Acts 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ ba ọkàn mi; nitori emi mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dàhun wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í se fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerúsálémù, nítorí orúkọ Jésù Olúwa.”