Acts 21:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn niti awọn Keferi ti o gbagbọ́, awa ti kọwe, a si ti pinnu rẹ̀ pe, ki nwọn pa ara wọn mọ kuro ninu ohun ti a fi rubọ si oriṣa, ati ẹ̀jẹ ati ohun ilọlọrùnpa, ati àgbere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùn pa, àti àgbérè.”