Acts 21:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keji, Paulu mú àwọn ọkunrin náà, ó ṣe ètò láti wẹ ẹ̀jẹ́ wọn kúrò, ati tirẹ̀ pẹlu. Ó wọ Tẹmpili lọ láti lọ ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ tí àkókò ìwẹ̀nùmọ́ wọn yóo parí, tí òun yóo mú ọrẹ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Paulu mu awọn ọkunrin na; ni ijọ keji o ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn, o si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o sọ ìgba ti ọjọ ìwẹ̀numọ́ na yio pé titi a fi rubọ fun olukuluku wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà; ní ijọ́ kéjì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹ́ḿpílì lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olukùlùkù wọn.