Acts 21:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ilu si rọ́, awọn enia si sure jọ: nwọn si mu Paulu, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu tẹmpili: lojukanna a si tì ilẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdo, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.