Acts 21:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li olori ogun sunmọ wọn, o si mu u, o paṣẹ pe ki a fi ẹ̀wọn meji dè e; o si bère ẹniti iṣe, ati ohun ti o ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì bèèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe.