Acts 21:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó gbà fún un, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó gbọ́wọ́ sókè kí àwọn eniyan lè dákẹ́. Nígbà tí wọ́n dákẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Heberu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si ti bùn u lãye, Paulu duro lori atẹgùn, o si juwọ́ si awọn enia. Nigbati nwọn si dakẹrọrọ o ba wọn sọrọ li ède Heberu, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wí pé: