Acts 22:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo dáhùn, mo ní, ‘Oluwa, àwọn gan-an mọ̀ pé èmi ni mo máa ń sọ àwọn tí ó bá gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, tí mo sì máa ń nà wọ́n káàkiri láti ilé ìpàdé kan dé ekeji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si wipe, Oluwa, awọn pãpã mọ̀ pe, emi a ti mã sọ awọn ti o gbà ọ gbọ sinu tubu, emi a si mã lù wọn ninu sinagogu gbogbo:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú sínágọ́gù kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́.