Acts 22:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ni ọ̀gágun bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wọ àgọ́ ọmọ-ogun lọ. Ó ní kí wọn nà án kí wọn fi wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, kí ó lè mọ ìdí tí àwọn eniyan ṣe ń pariwo lé e lórí bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olori ogun paṣẹ pe ki a mu u wá sinu ile-olodi, o ni ki a fi ẹgba bi i lẽre; ki on ki o le mọ̀ itori ohun ti nwọn ṣe nkigbe le e bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Pọ́ọ̀lù wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun baà lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.