Acts 22:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń dè é mọ́lẹ̀ láti máa nà án, Paulu bi balogun ọ̀rún tí ó dúró pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti na ọmọ-ìbílẹ̀ Romu láì tíì dá a lẹ́jọ́?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn si ti fi ọsán dè e, Paulu bi balogun ọrún ti o duro tì i pe, O ha tọ́ fun nyin lati nà ẹniti iṣe ará Romu li aijẹbi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sí tí fi okùn-ọṣán dè é, Pọ́ọ̀lù bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Róòmù ni àìdálẹ́bi bí?”