Acts 22:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ bá bìlà. Ẹ̀rù wá ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni Paulu, àtipé òun ti fi ẹ̀wọ̀n dè é.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn ti o mura lati bi i lẽre kuro lọdọ rẹ̀: lojukanna olori-ogun pẹlu si bẹ̀ru, nigbati o mọ̀ pe ara Romu ni iṣe, ati nitori o ti dè e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Ọlórí-ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní Pọ́ọ̀lù i ṣe, àti nítorí ó tí dè é.