Acts 22:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Juu ni mí, Tasu ní ilẹ̀ Silisia la gbé bí mi. Ní ìlú yìí ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Ilé-ìwé Gamalieli ni mo lọ, ó sì kọ́ mi dáradára nípa Òfin ìbílẹ̀ wa. Mo ní ìtara fún Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti ní lónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ju li emi iṣe ẹniti a bí ni Tarsu ilu kan ni Kilikia, ṣugbọn ti a tọ́ ni ilu yi, li ẹsẹ Gamalieli, ti a kọ́ gẹgẹ bi lile ofin awọn baba wa, ti mo si jẹ onitara fun Ọlọrun ani gẹgẹ bi gbogbo nyin ti ri li oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tásọ́sì ìlú kan ní Kílíkíà, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.