Acts 22:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lọ́jọ́ keji, ọ̀gágun náà tú Paulu sílẹ̀. Ó fẹ́ mọ òtítọ́ ẹ̀sùn tí àwọn Juu mú wá nípa rẹ̀. Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ. Ó bá mú Paulu lọ siwaju wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ijọ keji, nitoriti o fẹ mọ̀ dajudaju ohun ti awọn Ju nfi i sùn si, o tú u silẹ, o paṣẹ ki awọn olori alufa ati gbogbo igbimọ pejọ, o si mu Paulu sọkalẹ, o si mu u duro niwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ijọ́ kéjì, nítorí tí olórí-ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Pọ́ọ̀lù sùn sí, ó túu sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró ní wájú wọn.