Acts 23:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Juu péjọ pọ̀ láti dìtẹ̀ sí Paulu. Wọ́n búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ilẹ mọ́, awọn Ju kan dimọlu, nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ bẹ̃li awọn kì yio mu, titi awọn ó fi pa Paulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, awọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Pọ́ọ̀lù: