Acts 23:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A fẹ́ kí ẹ̀yin ati gbogbo wa ranṣẹ sí ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé kí ó fi Paulu ranṣẹ sí yín nítorí ẹ fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ní tiwa, a óo ti múra sílẹ̀ láti pa á kí ó tó dé ọ̀dọ̀ yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi ki ẹnyin pẹlu ajọ igbimọ wi fun olori-ogun, ki o mu u sọkalẹ tọ̀ nyin wá, bi ẹnipe ẹnyin nfẹ wadi ọ̀ran rẹ̀ dajudaju: ki o to sunmọ itosi, awa ó si ti mura lati pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ nísinsìn yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí-ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”