Acts 23:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọmọ arabinrin Paulu kan gbọ́ nípa ète yìí. Ó bá lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun, ó lọ ròyìn fún Paulu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọmọ arabinrin Paulu si gburó idena wọn, o lọ, o si wọ̀ inu ile-olodi lọ, o si sọ fun Paulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọmọ arabínrin Pọ́ọ̀lù sí gbúrò ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù.