Acts 23:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Balogun ọ̀rún náà bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun. Ó ní, “Ẹlẹ́wọ̀n tí ń jẹ́ Paulu ni ó pè mí, tí ó ní kí n mú ọdọmọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ yín nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fun yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O mu u, o si sìn i lọ sọdọ olori-ogun, o si wipe, Paulu ondè pè mi sọdọ rẹ̀, o si bẹ̀ mi pe ki emi mu ọmọkunrin yi tọ̀ ọ wá, ẹniti o ni nkan lati sọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí-ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Pọ́ọ̀lù òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sí bẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”