Acts 23:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọdọmọkunrin náà wá dáhùn pé, “Àwọn Juu ti fohùn ṣọ̀kan láti bẹ̀ yín pé kí ẹ mú Paulu wá siwaju ìgbìmọ̀ lọ́la kí àwọn le wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní fínnífínní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Awọn Ju fi ìmọ ṣọkan lati wá ibẹ̀ ọ ki o mu Paulu sọkalẹ wá si ajọ igbimọ li ọla, bi ẹnipe iwọ nfẹ bère nkan dajudaju nipa rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ sọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbimọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ bèèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.