Acts 23:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina máṣe gbọ́ tiwọn: nitori awọn ti o dèna dè e ninu wọn jù ogoji ọkunrin lọ, ti nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ, bẹ̃li awọn kì yio mu titi awọn o fi pa a: nisisiyi nwọn si ti mura tan, nwọn nreti idahùn lọdọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà má ṣe gbọ́ ti wọn: nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsìn yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”