Acts 23:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá sọ fún un pé, “N óo gbọ́ ẹjọ́ rẹ nígbà tí àwọn tí ó fi ẹjọ́ rẹ sùn náà bá dé.” Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ Paulu ní ààfin Hẹrọdu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O ni, Emi ó gbọ́ ẹjọ rẹ, nigbati awọn olufisùn rẹ pẹlu ba de. O si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa a mọ́ ni gbọ̀ngan idajọ Herodu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ní, “Èmi yóò gbọ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfiṣùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì paṣẹ pé kí wọn pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní abẹ́ àmójútó àwọn olùsọ́ ní gbọ̀ngán-ídájọ́ ààfin Hẹ́rọ́dù.