Acts 23:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si di ariwo nla: ninu awọn akọwe ti o wà li apa ti awọn Farisi dide, nwọn njà, wipe, Awa kò ri ohun buburu kan lara ọkunrin yi: ki si ni bi ẹmi kan tabi angẹli kan li o ba a sọ̀rọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisí dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí áńgẹ́lì kan tàbí ẹ̀mí kan ń baà sọ̀rọ̀?”