Acts 24:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gomina wá mi orí sí Paulu. Paulu wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Ó ní: “Ó dùn mọ́ mi pé níwájú yín ni n óo ti sọ ti ẹnu mi. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ ti ń ṣe onídàájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa yìí fún ọpọlọpọ ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati bãlẹ ṣapẹrẹ si i pe ki o sọ̀rọ, Paulu si dahùn wipe, Bi mo ti mọ̀ pe lati ọdún melo yi wá, ni iwọ ti ṣe onidajọ orilẹ-ede yi, tayọtayọ ni ng o fi wi ti ẹnu mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pe: “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀ tayọ̀ wí tí ẹnu mi.