Acts 24:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnìkan kò rí mi kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn ninu Tẹmpili. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò rí mi pé mo kó àwọn eniyan jọ láti dá rúkèrúdò sílẹ̀, ìbáà ṣe ninu ilé ìpàdé ni tabi níbikíbi láàrin ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn kò ri mi ni tẹmpili ki emi ki o ma ba ẹnikẹni jiyàn, bẹ̃li emi kò rú awọn enia soke, ibaṣe ninu sinagogu, tabi ni ilu:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnìkẹ́ni jiyàn nínú téḿpílì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú ṣínágọ́gù tàbí ní ibikíbi nínú ìlú: