Acts 24:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní: “Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a sí tí pè Pọ́ọ̀lù jáde, Tátúlù gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Fẹ́líkísì ó wí pé: “Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ lá ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsù rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí.