Acts 24:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si paṣẹ fun balogun ọrún kan pe, ki o mã ṣe itọju Paulu, ki o si bùn u làye, ati pe ki o máṣe dá awọn ojulumọ̀ rẹ̀ lẹkun, lati ma ṣe iranṣẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó fi Pọ́ọ̀lù sí a bẹ́ ìsọ́, ṣùgbọ́n kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.