Acts 25:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù láti dá ẹnìkẹ́ni lẹ́bí, kí ẹni tí a fiṣùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri àyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn,