Acts 25:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ni ijọ keji, ti Agrippa on Bernike wá, ti awọn ti ọsọ́ pipọ, ti nwọn si wọ ile ẹjọ, pẹlu awọn olori ogun, ati awọn enia nla ni ilu, Festu paṣẹ, nwọn si mu Paulu jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kejì, tí Àgírípà àti Báníkè wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀sọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Fẹ́sítúsì pàṣẹ, wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù jáde.