Acts 25:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Festu si wipe, Agrippa ọba, ati gbogbo ẹnyin enia ti o wà nihin pẹlu wa, ẹnyin ri ọkunrin yi, nitori ẹniti gbogbo ijọ awọn Ju ti rọgbaká mi, ni Jerusalemu ati nihinyi, ti nwọn nkigbe pe, Kò yẹ fun u lati wà lãye mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fẹ́sítúsì sì wí pé, “Àgírípà Ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ mi ni Jerúsálémù àti Kesaríà níhìn yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láàyè mọ́.