Acts 25:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerúsálémù ṣọ̀kalẹ̀ wá dúró yì í ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, tí wọn kò lè làdí rẹ̀.