Acts 26:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ṣe díẹ̀ ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni mo tì mọ́lé, lẹ́yìn tí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí alufaa. Wọn á máa pa wọ́n báyìí, èmi náà á sì ní bẹ́ẹ̀ gan-an ló yẹ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni mo si ṣe ni Jerusalemu: awọn pipọ ninu awọn enia mimọ́ ni mo há mọ́ inu tubu, nigbati mo ti gbà aṣẹ lọdọ awọn olori alufa; nigbati nwọn si npa wọn, mo li ohùn si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyi ni mo sì ṣe ni Jerúsálémù. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i.