Acts 26:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mò ń lọ láti ilé ìpàdé kan dé ekeji, mo sì ń jẹ wọ́n níyà, bóyá wọn a jẹ́ fẹnu wọn gbẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀tanú náà pọ̀ sí wọn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi lé wọn dé ìlú òkèèrè pàápàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbapipọ ni mo ṣẹ́ wọn niṣẹ ninu gbogbo sinagogu, mo ndù u lati mu wọn sọ ọrọ-odi; nigbati mo ṣoro si wọn gidigidi, mo ṣe inunibini si wọn de àjeji ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú ṣínágọ́gù dé inú ṣínágọ́gù, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì ṣí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.