Acts 26:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn dide, ki o si fi ẹsẹ rẹ tẹlẹ: nitori eyi ni mo ṣe farahàn ọ lati yàn ọ ni iranṣẹ ati ẹlẹri, fun ohun wọnni ti iwọ ti ri, ati ohun wọnni ti emi ó fi ara hàn fun ọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹṣẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fí ara hàn fún ọ: