Acts 26:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn mo kọ́kọ́ waasu fún àwọn tó wà ní Damasku, lẹ́yìn náà mo waasu fún àwọn tó wà ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo ilẹ̀ Judia, ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Mò ń kéde pé kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n yipada sí Ọlọrun, kí wọn máa ṣe ohun tí ó yẹ ẹni tí ó ti ronupiwada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn mo kọ́ sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalemu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Dámásíkù, àti ní Jerúsálémù, àti já gbogbo ilẹ Jùdíà, àti fún àwọn Kèfèrì, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwadà.