Acts 26:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Paulu dáhùn, ó ní, “Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọrun ni pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí ẹ rí bí mo ti rí lónìí, láìṣe ti ẹ̀wọ̀n yìí. Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan, ṣugbọn gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn: mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”