Acts 27:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó ní, “Ẹ̀yin ará, mo wòye pé ewu wà ninu ìrìn àjò yìí. Ọpọlọpọ nǹkan ni yóo ṣòfò: ẹrù inú ọkọ̀, ati ọkọ̀ fúnrarẹ̀. Ewu wà fún gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ pàápàá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Alàgba, mo woye pe iṣikọ̀ yi yio li ewu ati òfo pipọ, kì iṣe kìki ti ẹrù ati ti ọkọ̀, ṣugbọn ti ẹmí wa pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.”