Acts 27:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ibi tí wọ́n wà kì í ṣe ibi tí ó dára láti gbé ní ìgbà òtútù. Nítorí náà pupọ ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ rò pé kí àwọn kúrò níbẹ̀, bóyá wọn yóo lè dé Fonike níbi tí wọn yóo lè dúró ní ìgbà òtútù. Èbúté kan ní Kirete ni Fonike; ó kọjú sí ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn gúsù ati ìwọ̀ oòrùn àríwá Kirete.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nitori ebute na kò rọrùn lati lo akoko otutu nibẹ̀, awọn pipọ si damọran pe, ki a lọ kuro nibẹ̀, bi nwọn ó le làkàka de Fenike lati lo akoko otutu, ti iṣe ebute Krete ti o kọju si òsi ìwọ õrùn, ati ọtún ìwọ õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fóníkè, tí i ṣe èbúté Kírétè ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oorùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oorùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.