Acts 27:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si gbé e soke, nwọn nṣe iranlọwọ, nwọn ndì ọkọ ni isalẹ; nigbati nwọn si bẹ̀ru ki a ma ba gbá wọn sori iyanrìn diẹ̀, nwọn tagbokun, nwọn si ngbá kiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ́-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrin-dídẹ̀, wọn fi ìgbòkun sílẹ̀, bẹ́ẹ́ ni a sì ń gbá wa kiri.