Acts 27:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Pọ́ọ̀lù dìde láàrin wọn, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Kírétè, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa.