Acts 27:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati awọn atukọ̀ nwá ọ̀na ati sá kuro ninu ọkọ̀, ti nwọn si ti sọ igbaja kalẹ si oju okun bi ẹnipe nwọn nfẹ sọ idakọró silẹ niwaju ọkọ̀,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ ìgbàjá kalẹ̀ sí ojú òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.