Acts 27:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá já àwọn ìdákọ̀ró, wọ́n jẹ́ kí wọ́n rì sinu omi. Ní àkókò yìí kan náà, wọ́n tú okùn lára àwọn ajẹ̀ tí wọ́n fi ń tukọ̀. Wọ́n wá ta aṣọ-ọkọ̀ tí ó wà lókè patapata níwájú ọkọ̀. Atẹ́gùn wá ń fẹ́ ọkọ̀ lọ sí èbúté.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si ké idakọró kuro, nwọn jọ̀wọ wọn sinu okun, lẹsẹkanna nwọn tu ide ọkọ̀, nwọn si ta igbokun iwaju ọkọ̀ si afẹfẹ, nwọn wa kọju si ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbòkùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí-òkun.