Acts 27:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọkọ̀ rọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò jìn, ni ó bá dúró gbọnin. Iwájú ọkọ̀ wọ inú iyanrìn, kò ṣe é yí. Ẹ̀yìn ọkọ̀ kò kanlẹ̀, ìgbì wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ bí ó ti ń bì lù ú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí òkun méjì pàde, wọn fi orí-ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.