Acts 27:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn balogun ọ̀rún kò jẹ́ kí àwọn ọmọ-ogun ṣe ìfẹ́ inú wọn, nítorí pé ó fẹ́ mú Paulu gúnlẹ̀ ní alaafia. Ó pàṣẹ pé kí àwọn tí ó bá lè lúwẹ̀ẹ́ kọ́kọ́ bọ́ sómi, kí wọ́n lúwẹ̀ẹ́ lọ sí èbúté.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn balogun ọrún nfẹ gbà Paulu là, o kọ̀ ero wọn; o si paṣẹ fun awọn ti o le wẹ̀ ki nwọn ki o kọ́ bọ si okun lọ si ilẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Pọ́ọ̀lù là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí òkun lọ sì ilẹ̀.